Lineage

ORIKI IKIRUN

Ikirun agunbe omo onile obi , eleni ateeka eleni ewele, Omo eru ko gbodo dere ni jinini

Iwofa wa ko gbodo d’otonporo

Ibile agunbe ni ogb’ofa l’ori. Omo b’isu jin

na tan ma roun mu

b’onu,

Irele mo ko n’isa nile baba mi,

Irele ti mu ikirun r’okun ti mu r’osa

Irele ti mu ikirun dun gbongbon

Oya se tan Oya w’ole n’ile Ira

Obalufon se tan o w’ole l’Erin

Igbati Irele se tan lo wole nilu ikirun,

Pankere la n mu dubu osun nile baba tobi

mi lomo

Eeyan ti n re Ikirun Agunbe e ma wule mu

oko

d’ani,

Apata nla lo gba’le de Ikirun

Otontori baba onikaluku won lo mosu

lojosi,

Ikirun Omo Alakuko gagara ti nko lodo

Ona

. Ikirun Agunbe lasoro ana di baamiran

kojumo otomo, agbori oro pete, Omo moje

be, momu be, hinun bebe, meeri, meemo,

emi owi, eeh, gbogbo oro won yi

lomu’kirun Agunbe wumi